Amos 9:11-12

Ìmúpadàbọ̀ Israẹli

11 a“Ní ọjọ́ náà ní
Èmi yóò gbé àgọ́ Dafidi tí ó wó ró,
Èmi yóò dí odi rẹ̀ tí ó ya,
Èmi yóò sì gbé ahoro rẹ̀ sókè,
Èmi yóò sì kọ bí ti ọjọ́ ìgbàanì,
12kí wọn le jogún ìyókù Edomu
àti gbogbo àwọn kèfèrí, ti a ń pè nípa orúkọ mi,”
ni Olúwa, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí.
Copyright information for YorBMYO